Jump to content

Gbẹ̀du

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àtúnyẹ̀wò ní 09:52, 28 Oṣù Ṣẹ̀rẹ́ 2007 l'átọwọ́ Loadewole (ọ̀rọ̀ | àfikún)
(ìyàtọ̀) ← Àtúnyẹ̀wò tópẹ́ju | Àtúnyẹ̀wò ìsinsìnyí (ìyàtọ̀) | Àtúnyẹ̀wò tótuntunju → (ìyàtọ̀)

Gbedu Drum

GBÈDU:-

	Pàtàkì ni Gbedu jè nínú àwon ìlù ìbílè Yorùbá. Ìlù yii kannaa lawon kan n pen i àgbà. Ìyàńgèdè ni ìlè Yorùbá. 

Ìlù meta la le tokasi nínú owo ìlù Gbèdu.

(a) Aféré:- Ìlù nla ni afere. Ó ga tó iwòn esè bàtà mérin ó sì gùn gboogì. Géńdé ti ko ba dara re loju ko le gbe nìle. Oùn rè máa n rìnle dòdò. Ìkeke ni a fi maa nlù.

(b) Apéré tabi Opéré: Ìlù yii lo tobi tele afere labe omo ìlù ti a n pe ni Gbedu. Igi la fi gbee, sùgbón ko ga, ko si fe lenu to aféré.

(d) Obadan: Ìlù yii lo kere ju nínú òwó ìlù Gbedu. Igi la fi gbee bi ti awon yooku. Ko sit obi to apeere rara.

Gbedu se patakì pupo nitori pe o je ìlù oba. A kii dede n lu u. Ìlù yi wa fun ìyèsì awon Oba ilè Yorùbá. Bi oba ba gbese tabi ijoye nla kan teri gbaso won n lù Gbedu lati fi tufo.